bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 13
Hosea 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 14 →
1
Nígbà Éfúráímù bá ń ṣọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì, a gbé e ga ní Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀ṣùn pé ó ń sin òrìṣà Báálì, ó sì kú.
2
Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnra wọn ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Pé, Jẹ́ kí àwọn “Ènìyàn tí ń rúbọ fi ẹnu ko àwọn màluu ni ẹnu.”
3
Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkù òwúrọ̀, bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́, bí i èèpo ọkà tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé.
4
“Ṣùgbọ́n Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá. Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn èmi
5
Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní ihà ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi
6
Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.
7
Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún Èmi yóò farapamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.
8
Béárì igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbà Èmi yóò bá wọn jà bí? Èmi yóò sì fà wọ́n ya bí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya.
9
“A ti pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lì nítorí pé ìwọ lòdì sí mi ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ.
10
Níbo ni ọba rẹ gbé wà nìsisin yìí kí ó bá à le gbà ọ là? Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà, àwọn tí ẹ sọ pé, ‘Fún wa ní ọba àti ọmọ aládé’?
11
Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín lọ́ba Ninú ìbínú gbígbóná mi, Mo sì mú un kúrò
12
Ẹ̀bi Éfúráímù ni a tí ko jọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀
13
Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n Nígbà tí àsìkò tó, ó kọ̀ láti jáde síta láti inú.
14
“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú Ikú, àjàkálẹ̀-àrùn rẹ dà? Isà okú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́.
15
Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn láti ọ̀dọ̀ OLÚWA yóò wá, Yóò fẹ́ wá láti inú asálẹ̀ orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ kànga rẹ̀ yóò gbẹ pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀
16
Ará Sámáríà gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn. Wọn ó ti ipa idà ṣubú; a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14