bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 9
Hosea 9
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 10 →
1
Má ṣe yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì; má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀ èdè yòókù. Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìsòótọ́ si lọ́run yín. Ẹ fẹ́ràn láti gbowó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpàkà.
2
Àwọn ilé ìpàkà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀
3
Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé OLÚWA Éfúráímù yóò padà sí Éjíbítì Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ̀ ní Ásíríà.
4
Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún OLÚWA. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ńi wá sí orí tẹ́ḿpìlì OLÚWA
5
Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àsè yín tí a ti yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún OLÚWA?
6
Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Éjíbítì yóò kó wọn jọ, Mémúfísì yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ sílífa wọn ni yèrèpè yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn.
7
Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀; Àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé Jẹ́ kí Ísírẹ́lì mọ èyí Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni. A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀ A ka ẹni ìmísí sí asínwín.
8
Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ni olùṣọ́ ọ Éfúráímù. Ṣíbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀
9
Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gíbíà Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
10
“Nígbà tí mo rí Ísírẹ́lì, Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí èso àjàrà ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ Nígbà tí mo rí àwọn baba yín. Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí àkọ́so èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Baali-Péórì Wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni wọ́n di aláìmọ́ bí ohun tí wọ́n fẹ́ràn.
11
Ògo Éfúráímù yóò fò lọ bí ẹyẹ kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.
12
Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!
13
Mo rí Éfúráímù bí ìlú Tírúsì tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Éfúráímù yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”
14
Fún wọn, OLÚWA! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ.
15
“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gílígálì Mo kórìírà wọn níbẹ̀, Nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.
16
Éfúráímù ti rẹ̀ dànù Gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso, Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”
17
Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́ràn sí i; wọn yóò sì di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14