bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 4
Hosea 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 5 →
1
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí pé OLÚWA fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́ Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà
2
Afi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.
3
“Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.
4
“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹ̀nìkéjì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà
5
Ẹ ń ṣubú lọ́sàn-án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lúu yín Èmi ó pa ìyá rẹ run
6
Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀ “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfìn Ọlọ́run yín sílẹ̀ Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7
Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
8
Wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn mi Wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
9
Yóò wá ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí Èmi ó jẹ gbogbo wọn níyà nítorí ọ̀nà wọn. Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
10
“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; Wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ OLÚWA sílẹ̀
11
‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè, wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́ àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù
12
Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi Ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn sìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
13
Wọ́n ń rúbọ lórí àwọn òkè ńlá, Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré Lábẹ́ igi óákù, àti igi pópúlárì àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.
14
“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ilé òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
15
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Ísírẹ́lì Ìdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Júdà di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gílígálì. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Bẹti-Áfénì Ẹ má sì búra pé, ‘Bí OLÚWA ti wà láàyè nítòótọ́!’
16
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù Báwo wá ni OLÚWA ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
17
Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!
18
Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán wọ́n tún tẹ̀ṣíwájú nínú àgbèrè àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
19
Ìjì ni yóò gbá wọn lọ. Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14