bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 7
Hosea 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 8 →
1
Nígbà tí èmi ìbá mú Ísírẹ́lì láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúráímù ń farahàn ìwà búburú Ṣamáríà sì ń hàn síta Wọ́n ń ṣe èrú àwọn olè ń fọ́ ilé àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà
2
Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn: Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátapáta wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
3
“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn
4
Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5
Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara àwọn ọmọ aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
6
Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkísí, ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́ iná ní òwúrọ̀.
7
Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
8
“Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Éfúráímù jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
9
Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀, Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsíi
10
Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
11
“Éfúráímù dàbí àdàbà tó rọrùn láti tàn jẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Éjíbítì nísinsìn yìí tó sì tún ń padà lọ si Ásíríà.
12
Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀ Èmi nà wọ́n bí ìjọ ènìyàn wọn ti gbọ́
13
Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi yóò rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
14
Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùn réré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15
Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, ṣíbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16
Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá ògo; Wọ́n dàbí ọrun tí ó wà fún ìtànjẹ́ Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí irúnú ahọ́n wọn. Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Éjíbítì.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14