bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 12
Proverbs 12
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 13 →
1
ẸNIKẸNI ti o fẹ ẹkọ́, o fẹ ìmọ: ṣugbọn ẹniti o korira ibawi, ẹranko ni.
2
Enia rere ni ojurere lọdọ Oluwa: ṣugbọn enia ete buburu ni yio dalẹbi.
3
A kì yio fi ẹsẹ enia mulẹ nipa ìwa-buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo kì yio fatu.
4
Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rẹ̀: ṣugbọn eyi ti ndojuti ni dabi ọyún ninu egungun rẹ̀.
5
Ìro olododo tọ́: ṣugbọn ìgbimọ awọn enia buburu, ẹ̀tan ni.
6
Ọ̀rọ enia buburu ni lati luba fun ẹ̀jẹ: ṣugbọn ẹnu aduro-ṣinsin ni yio gbà wọn silẹ.
7
A bì enia buburu ṣubu, nwọn kò si si: ṣugbọn ile olododo ni yio duro.
8
A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn.
9
Ẹniti a ngàn, ti o si ni ọmọ-ọdọ, o san jù ẹ̀niti nyìn ara rẹ̀ ti kò si ni onjẹ.
10
Olododo enia mọ̀ ãjo ẹmi ẹran rẹ̀: ṣugbọn iyọ́nu awọn enia buburu, ìka ni.
11
Ẹniti o ro ilẹ rẹ̀ li a o fi onjẹ tẹlọrun: ṣugbọn ẹniti ntọ̀ enia-lasan lẹhin ni oye kù fun.
12
Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso.
13
Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju.
14
Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u.
15
Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n.
16
Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ.
17
Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan.
18
Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni.
19
Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni.
20
Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni.
21
Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi.
22
Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀.
23
Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere.
24
Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn.
25
Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀.
26
Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ.
27
Ọlẹ enia kò mu ohun ọdẹ rẹ̀; ṣugbọn lati jẹ alãpọn enia, ọrọ̀ iyebiye ni.
28
Li ọ̀na olododo ni ìye; ikú kò si loju ọ̀na otitọ.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31