bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 28
Proverbs 28
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 29 →
1
ENIA buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun.
2
Nipa irekọja ilẹ li awọn ijoye idi pupọ, ṣugbọn nipa amoye ati oni ìmọ̀ enia kan, li a mu ilẹ pẹ.
3
Olupọnju ti o nni olupọnju lara, o dabi agbalọ òjo ti kò fi onjẹ silẹ.
4
Awọn ti o kọ̀ ofin silẹ a ma yìn enia buburu: ṣugbọn awọn ti o pa ofin mọ́ a ma binu si wọn.
5
Oye idajọ kò ye enia buburu: ṣugbọn awọn ti nṣe afẹri Oluwa moye ohun gbogbo.
6
Talaka ti nrin ninu iduro-ṣinṣin rẹ̀, o san jù alarekereke ìwa, bi o tilẹ ṣe ọlọrọ̀.
7
Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́, o ṣe ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ṣe ẹlẹgbẹ jẹguduragudu, o dojuti baba rẹ̀.
8
Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka.
9
Ẹniti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ pãpa yio di irira.
10
Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere.
11
Ọlọrọ̀ gbọ́n li oju ara rẹ̀: ṣugbọn talaka ti o moye ridi rẹ̀.
12
Nigbati awọn olododo enia ba nyọ̀, ọṣọ́ nla a wà; ṣugbọn nigbati enia buburu ba dide, enia a sá pamọ́.
13
Ẹniti o bo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọlẹ kì yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ̀ ọ silẹ yio ri ãnu.
14
Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru nigbagbogbo: ṣugbọn ẹniti o ba sé aiya rẹ̀ le ni yio ṣubu sinu ibi.
15
Bi kiniun ti nke ramùramu, ati ẹranko beari ti nfi ebi sare kiri; bẹ̃ni ẹni buburu ti o joye lori awọn talaka.
16
Ọmọ-alade ti o ṣe alaimoye pupọ ni iṣe ìwa-ika pupọ pẹlu: ṣugbọn eyiti o korira ojukokoro yio mu ọjọ rẹ̀ pẹ.
17
Enia ti o ba hù ìwa-ika si ẹ̀jẹ ẹnikeji, yio sá lọ si ihò: ki ẹnikan ki o máṣe mu u.
18
Ẹnikẹni ti o ba nrin dẽde ni yio là: ṣugbọn ẹniti o nfi ayidayida rìn loju ọ̀na meji, yio ṣubu ninu ọkan ninu wọn.
19
Ẹniti o ba ro ilẹ rẹ̀ yio li ọ̀pọ onjẹ: ṣugbọn ẹniti o ba ntọ̀ enia asan lẹhin yio ni òṣi to.
20
Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya.
21
Iṣojuṣãju enia kò dara: nitoripe fun òkele onjẹ kan, ọkunrin na yio ṣẹ̀.
22
Ẹniti o kanju ati là, o li oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀wá ta on.
23
Ẹniti o ba enia wi yio ri ojurere ni ikẹhin jù ẹniti nfi ahọn pọn ọ lọ.
24
Ẹnikẹni ti o ba nja baba tabi iya rẹ̀ li ole, ti o si wipe, kì iṣe ẹ̀ṣẹ; on na li ẹgbẹ apanirun.
25
Ẹniti o ṣe agberaga li aiya, a rú ìja soke, ṣugbọn ẹniti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o mu sanra.
26
Ẹniti o gbẹkẹ le aiya ara rẹ̀, aṣiwère ni; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nfi ọgbọ́n rìn, on li a o gbà la.
27
Ẹniti o ba nfi fun olupọnju kì yio ṣe alaini: ṣugbọn ẹniti o mu oju rẹ̀ kuro, yio gbà egún pupọ.
28
Nigbati enia buburu ba hù, awọn enia a sá pamọ́: ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣegbe, awọn olododo a ma pọ̀ si i.
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31