bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 29
Proverbs 29
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 30 →
1
ẸNITI a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe.
2
Nigbati awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ̀; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn.
3
Ẹnikẹni ti o fẹ ọgbọ́n, a mu baba rẹ̀ yọ̀: ṣugbọn ẹniti o mba panṣaga kẹgbẹ, a ba ọrọ̀ rẹ̀ jẹ.
4
Nipa idajọ li ọba imu ilẹ tòro: ṣugbọn ẹniti o ba ngbà ọrẹ a bì i ṣubu.
5
Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀.
6
Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀.
7
Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o.
8
Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro.
9
Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si.
10
Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀.
11
Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin.
12
Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru.
13
Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji.
14
Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai.
15
Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀.
16
Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn.
17
Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn.
18
Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́.
19
A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn.
20
Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
21
Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀.
22
Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja.
23
Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá.
24
Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan.
25
Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke.
26
Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá.
27
Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo: ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọ̀na, irira ni si enia buburu.
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31