bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 27
Proverbs 27
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
1
MÁṢE leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ̀ ohun ti ọjọ kan yio hù jade.
2
Jẹ ki ẹlomiran ki o yìn ọ, ki o máṣe ẹnu ara rẹ; alejo, ki o má si ṣe ète ara rẹ.
3
Okuta wuwo, yanrin si wuwo, ṣugbọn ibinu aṣiwère, o wuwo jù mejeji lọ.
4
Ibinu ni ìka, irunu si ni kikún-omi; ṣugbọn tani yio duro niwaju owú.
5
Ibawi nigbangba, o san jù ifẹ ti o farasin lọ.
6
Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́: ṣugbọn ifẹnukonu ọta li ẹ̀tan.
7
Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin; ṣugbọn ọkàn ti ebi npa, ohun kikoro gbogbo li o dùn.
8
Bi ẹiyẹ ti ima fò kiri lati inu itẹ́ rẹ̀, bẹ̃li enia ti o nrìn kiri jina si ipò rẹ̀.
9
Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa.
10
Ọrẹ́ rẹ ati ọrẹ́ baba rẹ, máṣe kọ̀ silẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe lọ si ile arakunrin li ọjọ idãmu rẹ: nitoripe aladugbo ti o sunmọ ni, o san jù arakunrin ti o jina rere lọ.
11
Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn.
12
Amoye enia ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn awọn òpe kọja a si jẹ wọn niya.
13
Gbà aṣọ rẹ̀ nitoriti o ṣe onigbọwọ alejo, si gbà ohun ẹri lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.
14
Ẹniti o ba ndide ni kutukutu ti o nfi ohùn rara kí ọrẹ́ rẹ̀, egún li a o kà a si fun u.
15
Ọṣọrọ-òjo li ọjọ òjo, ati onija obinrin, bakanna ni.
16
Ẹnikẹni ti o pa a mọ́, o pa ẹfũfu mọ́, ororo ọwọ-ọtún rẹ̀ yio si fihàn.
17
Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀.
18
Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun.
19
Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia.
20
Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia.
21
Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀.
22
Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ.
23
Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ.
24
Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran?
25
Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀.
26
Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye-owo oko.
27
Iwọ o si ni wàra ewurẹ to fun onjẹ rẹ, fun onjẹ awọn ara ile rẹ, ati fun onjẹ awọn iranṣẹ-birin rẹ.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31