bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 15
Proverbs 15
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 16 →
1
IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke.
2
Ahọn ọlọgbọ́n nlò ìmọ rere: ṣugbọn ẹnu aṣiwère a ma gufẹ wère.
3
Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere.
4
Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn.
5
Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye.
6
Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu.
7
Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃.
8
Ẹbọ awọn enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rẹ̀.
9
Ọ̀na enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn o fẹ ẹniti ntọ̀ ododo lẹhin.
10
Ikilọ kikan wà fun ẹniti o kọ̀ ọ̀na silẹ; ẹniti o ba si korira ibawi yio kú.
11
Ipo-okú ati iparun ṣi silẹ niwaju Oluwa; njẹ melomelo li aiya awọn ọmọ enia.
12
Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ.
13
Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.
14
Aiya ẹniti oye ye nṣe afẹri ìmọ; ṣugbọn ẹnu aṣiwère nfi wère bọ́ ara rẹ̀.
15
Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo.
16
Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀.
17
Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
18
Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu.
19
Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni.
20
Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe ayọ̀ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rẹ̀.
21
Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin.
22
Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ.
23
Enia ni ayọ̀ nipa idahùn ẹnu rẹ̀; ati ọ̀rọ kan li akoko rẹ̀, o ti wọ̀ to?
24
Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ.
25
Oluwa yio run ile agberaga; ṣugbọn yio fi ìpãlà opó kalẹ.
26
Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀.
27
Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè.
28
Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade.
29
Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo.
30
Imọlẹ oju mu inu dùn; ihin rere si mu egungun sanra.
31
Ẹniti o ba gbọ́ ibawi ìye, a joko lãrin awọn ọlọgbọ́n.
32
Ẹniti o kọ̀ ẹkọ́, o gàn ọkàn ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba gbọ́ ibawi, o ni imoye.
33
Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31