bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 19
Proverbs 19
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 20 →
1
TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère.
2
Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu.
3
Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa.
4
Ọrọ̀ fà ọrẹ́ pupọ; ṣugbọn talaka di yiyà kuro lọdọ aladugbo rẹ̀.
5
Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ.
6
Ọpọlọpọ ni yio ma bẹ̀bẹ ojurere ọmọ-alade: olukuluku enia ni si iṣe ọrẹ́ ẹniti ntani li ọrẹ.
7
Gbogbo awọn arakunrin talaka ni ikorira rẹ̀: melomelo ni awọn ọrẹ́ rẹ̀ yio ha jina si i? o ntẹle ọ̀rọ wọn, ṣugbọn nwọn kò si.
8
Ẹniti o gbọ́n, o fẹ ọkàn ara rẹ̀: ẹniti o pa oye mọ́ yio ri rere.
9
Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ẹniti o si nṣeke yio ṣegbe.
10
Ohun rere kò yẹ fun aṣiwère; tabi melomelo fun iranṣẹ lati ṣe olori awọn ijoye.
11
Imoye enia mu u lọra ati binu; ogo rẹ̀ si ni lati ré ẹ̀ṣẹ kọja.
12
Ibinu ọba dabi igbe kiniun; ṣugbọn ọjurere rẹ̀ dabi ìri lara koriko.
13
Aṣiwère ọmọ ni ibanujẹ baba rẹ̀: ìja aya dabi ọ̀ṣọrọ òjo.
14
Ile ati ọrọ̀ li ogún awọn baba: ṣugbọn amoye aya, lati ọdọ Oluwa wá ni.
15
Imẹlẹ mu ni sun orun fọnfọn; ọkàn ọlẹ li ebi yio si pa.
16
Ẹniti o pa ofin mọ́, o pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ba kẹgàn ọ̀na rẹ̀ yio kú.
17
Ẹniti o ṣãnu fun talaka Oluwa li o win; ati iṣeun rẹ̀, yio san a pada fun u.
18
Nà ọmọ rẹ nigbati ireti wà, má si ṣe gbe ọkàn rẹ le ati pa a.
19
Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e.
20
Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ.
21
Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro.
22
Ẹwà enia ni iṣeun rẹ̀: talaka enia si san jù eleke lọ.
23
Ibẹ̀ru Oluwa tẹ̀ si ìye: ẹniti o ni i yio joko ni itẹlọrun; a kì yio fi ibi bẹ̀ ẹ wọ́.
24
Imẹlẹ enia kì ọwọ rẹ̀ sinu iṣasun, kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu ara rẹ̀.
25
Lu ẹlẹgàn, òpe yio si kiyesi ara: si ba ẹniti o moye wi, oye ìmọ yio si ye e.
26
Ẹniti o ba nṣìka si baba rẹ̀, ti o si le iya rẹ̀ jade, on li ọmọ ti nṣe itiju, ti o si mu ẹ̀gan wá.
27
Ọmọ mi, dẹkun ati fetisi ẹkọ́ ti imu ni ṣìna kuro ninu ọ̀rọ ìmọ.
28
Ẹlẹri buburu fi idajọ ṣẹsin: ẹnu enia buburu si gbe aiṣedẽde mì.
29
A pèse ọ̀rọ-idajọ fun awọn ẹlẹgàn, ati paṣan fun ẹ̀hin awọn aṣiwère.
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 20 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31