bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 20
Proverbs 20
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 21 →
1
ẸLẸYA li ọti-waini, alariwo li ọti lile, ẹnikẹni ti a ba fi tanjẹ kò gbọ́n.
2
Ibẹ̀ru ọba dabi igbe kiniun: ẹnikẹni ti o ba mu u binu, o ṣẹ̀ si ọkàn ara rẹ̀.
3
Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja: ṣugbọn olukuluku aṣiwère ni ima ja ìja nla.
4
Ọlẹ kò jẹ tu ilẹ nitori otutu; nitorina ni yio fi ma ṣagbe nigba ikore, kì yio si ni nkan.
5
Ìmọ ninu ọkàn enia dabi omi jijin; ṣugbọn amoye enia ni ifà a jade.
6
Ọ̀pọlọpọ enia ni ima fọnrere, olukuluku ọrẹ ara rẹ̀: ṣugbọn olõtọ enia tani yio ri i.
7
Olõtọ enia nrìn ninu iwa-titọ rẹ̀: ibukún si ni fun awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀!
8
Ọba ti o joko lori itẹ́ idajọ, o fi oju rẹ̀ fọ́n ìwa-ibi gbogbo ka.
9
Tali o le wipe, Mo ti mu aiya mi mọ́, emi ti mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi?
10
Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, bakanna ni mejeji ṣe irira loju Oluwa.
11
Iṣe ọmọde pãpa li a fi imọ̀ ọ, bi ìwa rẹ̀ ṣe rere ati titọ.
12
Eti igbọ́ ati oju irí, Oluwa li o ti dá awọn mejeji.
13
Máṣe fẹ orun sisùn, ki iwọ ki o má ba di talaka; ṣi oju rẹ, a o si fi onjẹ tẹ ọ lọrùn.
14
Kò ni lãri, kò ni lãri li oníbárà iwi; ṣugbọn nigbati o ba bọ si ọ̀na rẹ̀, nigbana ni iṣogo.
15
Wura wà ati iyùn ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn ète ìmọ, èlo iyebiye ni.
16
Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.
17
Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún.
18
Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun.
19
Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire.
20
Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri.
21
Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀.
22
Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ.
23
Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, irira ni loju Oluwa; ìwọn irẹjẹ kò si dara.
24
Irin ti enia nrìn, lati ọdọ Oluwa ni; tani ninu awọn enia ti o le mọ̀ ọ̀na rẹ̀?
25
Idẹkùn ni fun enia lati yara ṣe ileri mimọ́, ati lẹhin ẹjẹ́, ki o ma ronu.
26
Ọlọgbọ́n ọba a tú enia buburu ka, a si mu ayika-kẹkẹ́ rẹ̀ kọja lori wọn.
27
Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma ṣe awari iyara inu.
28
Anu ati otitọ pa ọba mọ́: ãnu li a si fi ndi itẹ́ rẹ̀ mu.
29
Ogo awọn ọdọmọkunrin li agbara wọn: ẹwà awọn arugbo li ewú.
30
Apá ọgbẹ ni iwẹ̀ ibi nù kuro: bẹ̃ si ni ìna ti o wọ̀ odò ikùn lọ.
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31