bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 18
Proverbs 18
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 19 →
1
ẸNITI o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀, yio si kọju ìja nla si ohunkohun ti iṣe ti oye.
2
Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn.
3
Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju.
4
Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn.
5
Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ.
6
Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá.
7
Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀.
8
Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
9
Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.
10
Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.
11
Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀.
12
Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ.
13
Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u.
14
Ọkàn enia yio faiyàrán ailera rẹ̀; ṣugbọn ọkàn ti o rẹ̀wẹsi, tani yio gbà a?
15
Aiya amoye ni ìmọ; eti ọlọgbọ́n a si ma ṣe afẹri ìmọ.
16
Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla.
17
Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ.
18
Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.
19
Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin.
20
Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu.
21
Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.
22
Ẹnikẹni ti o ri aya fẹ, o ri ohun rere, o si ri ojurere lọdọ Oluwa.
23
Talaka a ma bẹ̀ ẹ̀bẹ; ṣugbọn ọlọrọ̀ a ma fi ikanra dahùn.
24
Ẹniti o ni ọrẹ́ pupọ, o ṣe e si iparun ara rẹ̀; ọrẹ́ kan si mbẹ ti o fi ara mọni ju arakunrin lọ.
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 19 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31