bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 16
Proverbs 16
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
1
IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn.
2
Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn.
3
Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ.
4
Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi.
5
Olukulùku enia ti o gberaga li aiya, irira ni loju Oluwa: bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, kì yio wà laijiya.
6
Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi.
7
Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia.
8
Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́.
9
Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀.
10
Ọrọ isọtẹlẹ mbẹ li ète ọba: ẹnu rẹ̀ kì iṣẹ̀ ni idajọ.
11
Iwọn ati òṣuwọn otitọ ni ti Oluwa: gbogbo okuta-ìwọn àpo, iṣẹ rẹ̀ ni.
12
Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li a ti fi idi itẹ́ kalẹ.
13
Ete ododo ni didùn-inu awọn ọba: nwọn si fẹ ẹniti nsọ̀rọ titọ.
14
Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u.
15
Ni imọlẹ oju ọba ni ìye; ojurere rẹ̀ si dabi awọsanma òjo arọkuro.
16
Lati ni ọgbọ́n, melomelo li o san jù wura lọ; ati lati ni oye, melomelo li o dara jù fadaka lọ.
17
Òpopo-ọ̀na awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi: ẹniti o pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́.
18
Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu.
19
O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun.
20
Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u.
21
Ọlọgbọ́n aiya li a o pè li amoye: didùn-ète a si ma mu ẹkọ́ pọ̀.
22
Oye li orisun ìye fun ẹniti o ni i: ṣugbọn ẹkọ́ aṣiwère ni iwère.
23
Aiya ọlọgbọ́n mu ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, o si mu ẹkọ́ pọ̀ li ète rẹ̀.
24
Ọrọ didùn dabi afara oyin, o dùn mọ ọkàn, o si ṣe ilera fun egungun.
25
Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú.
26
Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e.
27
Enia-buburu hù ìwa-ibi jade, ati li ète rẹ̀ bi ẹnipe iná jijo li o wà nibẹ.
28
Alayidayida enia dá ìja silẹ: asọ̀rọkẹlẹ yà awọn ọrẹ́ ni ipa.
29
Ẹni ìwa-agbara tàn aladugbo rẹ̀, a si mu u lọ si ipa-ọ̀na ti kò dara.
30
On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu.
31
Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo.
32
Ẹniti o lọra ati binu, o san jù alagbara lọ; ẹniti o si ṣe akoso ẹmi rẹ̀, o jù ẹniti o ṣẹgun ilu lọ.
33
A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31