bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Proverbs 14
Proverbs 14
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 15 →
1
ỌLUKULUKU ọlọgbọ́n obinrin ni kọ́ ile rẹ̀: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ ara rẹ̀ fà a lulẹ.
2
Ẹniti o nrìn ni iduroṣiṣin rẹ̀ o bẹ̀ru Oluwa: ṣugbọn ẹniti o ṣe arekereke li ọ̀na rẹ̀, o gàn a.
3
Li ẹnu aṣiwere ni paṣan igberaga; ṣugbọn ète awọn ọlọgbọ́n ni yio pa wọn mọ́.
4
Nibiti malu kò si, ibujẹ a di ofo: ṣugbọn ibisi pupọ mbẹ nipa agbara malu.
5
Ẹlẹri olõtọ kò jẹ ṣeke: ṣugbọn ẹ̀tan li ẹlẹri eke ima sọ jade.
6
Ẹlẹgan nwá ọgbọ́n, kò si ri i: ṣugbọn ìmọ kò ṣoro fun ẹniti oye ye.
7
Kuro niwaju aṣiwere, ati lọdọ ẹniti kò ni ète ìmọ.
8
Ọgbọ́n amoye ni ati moye ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn iwere awọn aṣiwere li ẹ̀tan.
9
Aṣiwere nfi ẹbi-ẹ̀ṣẹ ṣẹsin: ṣugbọn ojurere wà larin awọn olododo.
10
Aiya mọ̀ ikoro ara rẹ̀; alejo kò si ni iṣe pẹlu ayọ̀ rẹ̀.
11
Ile enia buburu li a o run: ṣugbọn agọ ẹni diduroṣinṣin ni yio ma gbilẹ.
12
Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú.
13
Ninu ẹrín pẹlu, aiya a ma kãnu; ati li opin, ayọ̀ a di ibinujẹ.
14
Apadasẹhin li aiya ni itẹlọrun lati inu ọ̀na ara rẹ̀: ṣugbọn enia rere lati inu ohun ti iṣe tirẹ̀.
15
Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere.
16
Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju.
17
Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira.
18
Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade.
19
Awọn ẹni-buburu tẹriba niwaju awọn ẹnirere; ati awọn enia buburu li ẹnu-ọ̀na awọn olododo.
20
A tilẹ korira talaka lati ọdọ aladugbo rẹ̀ wá: ṣugbọn ọlọrọ̀ ni ọrẹ́ pupọ.
21
Ẹniti o kẹgàn ẹnikeji rẹ̀, o ṣẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba ṣãnu fun awọn talaka, ibukún ni fun u.
22
Awọn ti ngbìmọ buburu kò ha ṣina bi? ṣugbọn ãnu ati otitọ ni fun awọn ti ngbìmọ ire.
23
Ninu gbogbo lãla li ère pupọ wà: ṣugbọn ọ̀rọ-ẹnu, lasan ni.
24
Adé awọn ọlọgbọ́n li ọrọ̀ wọn: ṣugbọn iwère awọn aṣiwère ni wère.
25
Olõtọ ẹlẹri gbà ọkàn silẹ: ṣugbọn ẹlẹri ẹ̀tan sọ̀rọ eke.
26
Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀.
27
Ibẹ̀ru Oluwa li orisun ìye, lati kuro ninu ikẹkùn ikú.
28
Ninu ọ̀pọlọpọ enia li ọlá ọba: ṣugbọn ninu enia diẹ ni iparun ijoye.
29
Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke.
30
Ọkàn ti o yè kõro ni ìye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun.
31
Ẹniti o ba nni talaka lara, o gàn Ẹlẹda rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o ṣãnu fun talaka o bu ọlá fun u.
32
A pa enia buburu run ninu ìwa-buburu rẹ̀; ṣugbọn olododo ni ireti ninu ikú rẹ̀.
33
Ọgbọ́n fi idi kalẹ li aiya ẹniti o moye; ṣugbọn a fi i hàn laiya awọn aṣiwère.
34
Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn ẹ̀ṣẹ li ẹ̀gan orilẹ-ède.
35
Ojurere ọba mbẹ li ọdọ ọlọgbọ́n iranṣẹ; ṣugbọn ibinu rẹ̀ si iranṣẹ ti nhùwa itiju.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31