bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 1
2 Chronicles 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 2 →
1
Sólómónì ọmọ Dáfídì fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀. Nítorí tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọpọ̀.
2
Nígbà náà, Sólómónì bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ sí àwọn alákóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Ísírẹ́lì, àwọn olórí ìdílé
3
Pẹ̀lú Sólómónì, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gíbíónì, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Móse ìránṣẹ́ OLÚWA ti kọ́ ni ihà.
4
Nísinsinyìí, Dáfídì ti gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jéárímù sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jérúsálẹ́mù.
5
Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrù, ti ṣe wà ní Gíbíónì níwájú àgọ́ OLÚWA: Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì àti gbogbo àpèjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀.
6
Sólómónì gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú OLÚWA ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀run ọrẹ sísun lórí rẹ̀.
7
Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Sólómónì, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.”
8
Sólómónì dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dáfídì baba à mi ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
9
Nísinsinyìí OLÚWA Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dáfídì di mímúsẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lóri àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.
10
Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ́nà, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?”
11
Ọlọ́run wí fún Solómónì pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí,
12
Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”
13
Nígbà náà ni Sólómónì sì ti ibi gígá Gíbíónì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti iwájú àgọ́ ìpàde. Ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì.
14
Sólómónì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹsin jọ, ó sì ní ẹgbàáje kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàafà ẹlẹ́sin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù
15
ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jérúsálẹ́mù bí òkúta, àti Kédárì ó pọ̀ bí igi Síkámórè ní àwọn ẹsẹ̀ òkè.
16
Àwọn ẹsin Sólómónì ní a gbà láti ìlú òkèrè Éjíbítì àti láti kúè oníṣòwò ti ọba ni ó rà wọ́n láti Kúè.
17
Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Éjíbítì. Fún ọgọ́rùn ún mẹ́fà Sékélì (6,000) fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin-méjì-ó-dínláàdọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hítì àti ti àwọn ará Árámíà.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36