bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 12
2 Chronicles 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
1
Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ipò Réhóbóámù gẹ́gẹ́ bí ọba lélẹ̀, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Ísírẹ́lì, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin OLÚWA tì.
2
Nítorí tí wọn kò ṣọ̀ọ́tọ́ sí OLÚWA. Ṣíṣákì ọba Ị́jíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù ní ọdún karùnún ti ọba Réhóbóamù
3
Pẹ̀lú ẹgbẹ̀fà kẹ̀kẹ́ (12, 000) àti ọkẹ́ mẹ́ta àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Líbíyánì, Ṣúkísè àti Kúṣì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Éjíbítì.
4
Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Júdà, pẹ̀lú wá sí Jérúsálẹ́mù bí ó ti jìnnà tó.
5
Nígbà naà, wòlíì Ṣémáíà wá sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Júdà tí wọ́n ti péjọ ní Jérúsálẹ́mù nítorí ìbẹ̀rù Ṣíṣáki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣíṣákì.”
6
Àwọn olórí Ísírẹ́lì àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Olódodo ni OLÚWA.”
7
Nígbà tí OLÚWA ríi pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ OLÚWA yí tọ Ṣémáíà lọ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jérúsálẹ́mù ní pasẹ̀ Ṣíṣákì.
8
Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàárin sísìn mí àti sísin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.”
9
Nígbà tí Ṣíṣákì ọba Éjíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù, ó gbé àwọn ìṣúra ilé OLÚWA, àti àwọn ìsúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Sólómónì dá.
10
Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Réhóbóámù dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùsọ́ tí ó wà ní ẹnu isẹ́ ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́.
11
Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé OLÚWA, àwọn olùsọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn apáta naà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́.
12
Nítori ti Réhóbóámù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú OLÚWA yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì paárun pátapáta. Nítòótọ́, ire díẹ̀ wà ní Júdà.
13
Ọba Réhóbóámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí OLÚWA ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ sí.
14
O sì ṣe búburú, nítorí tí kò múra ọkàn rẹ̀ láti wá OLÚWA.
15
Fún tí iṣẹ́ ìjọba Réhóbóámù láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrantí ti Ṣémáíà wòlíì àti ti Idò, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá? Ìtẹ̀ṣíwájú ogun jíjà sì wà láàárin Réhóbóámù àti Jéróbóámù.
16
Réhóbóámù sinmi sínú ìlú ńlá ti Dáfídì. Ábíjà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36