bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 3
2 Chronicles 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 4 →
1
Nígbà náà, Sólómónì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù lórí òkè Móríà, níbi tí OLÚWA ti farahan bàbá a rẹ̀ Dáfídì. Ní ori ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì, ibi tí Dáfídì pèsè.
2
Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹ́rin ìjọba rẹ̀.
3
Ìpìlẹ̀ tí Sólómónì gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ (lílo ìgbọ̀nwọ́ tí tẹ́lẹ̀)
4
Ìloro tí ó wà níwájú ilé OLÚWA náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́. Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà.
5
Ó fi igi fírì bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bòó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.
6
Ó se ilé OLÚWA náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Góòlù tí ó lò jẹ́ wúrà párifáímù.
7
Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLÚWA Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.
8
Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé OLÚWA mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà talẹ́ntì ti wúrà dáradára.
9
Ìwọn àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta Ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.
10
Ní ibi mímọ́ jùlọ, ógbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà.
11
Iye ìyẹ́ apá ìbú atẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé OLÚWA. Nígbà tí ìyẹ́ apa kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-un ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.
12
Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ní ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé OLÚWA mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú. Tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.
13
Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyìí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà.
14
Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a se sórí i rẹ̀.
15
Níwájú ilé OLÚWA náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn ún.
16
Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rin Pomígíránátìo (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà
17
Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé OLÚWA, ọ̀kan sí gúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúsù, ó ṣe ní Jákínì àti èyí ti àríwá, ó ṣe ní Bóásì.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36