bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 10
2 Chronicles 10
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 11 →
1
Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba.
2
Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì gbọ́ èyí ó wà ní Éjíbítì, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Sólómónì ó sì padà láti Éjíbítì.
3
Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránsẹ́ sí Jéróbóámù àti òun àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì lọ sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù wọ́n sì wí fún pé:
4
“Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.”
5
Réhóbóámù sì dáhùn pé, “ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà sì lọ.
6
Nígbà náà ni ọba Réhóbóámù fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbààgbà tí ó ti ń sin Baba rẹ̀ Sólómónì nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”.
7
Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ire fún wọn kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.”
8
Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbààgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbà sókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀.
9
Ó sì bèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’ ”
10
Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́, wí fún wọn, pé ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ.
11
Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo jùlọ. Baba mi fi pàṣán nà yín pẹ̀lú ẹgba: Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ”
12
Ní ọjọ́ kẹ̀ta Jéróbóámù àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹ̀ta.”
13
Ọba sì dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Ó kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbààgbà,
14
Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; Èmi yóò sì mú kí ó wúwo jùlọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèé.”
15
Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì tẹ́tísi àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ OLÚWA ṣẹ tí a ti sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì nípasẹ̀ Áhíjà ará Ṣilò.
16
Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé: “Ìpín kí ní a ní nínú Dáfídì, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jésè? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ìwọ Ísírẹ́lì! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dáfídì!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ilé wọn.
17
Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní ìlú Júdà, Réhóbóámù pàpà ń jọba lórí wọn.
18
Ọba Réhóbóámù rán Ádónírámù jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúuru, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Réhóbóámù bí ó tí wù kí ó rí, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jérúsálẹ́mù.
19
Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì sì wà ní ìsọ̀tẹ̀ lórí ilé Dáfídì títí fi di òní yìí.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36