bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 13
2 Chronicles 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 14 →
1
Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù, Ábíjà di ọba Júdà.
2
Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mákà, ọmọbìnrin Úríélì ti Gíbéà. Ogun wà láàárin Ábíjà àti Jéróbóámù.
3
Ábíjà lọ sí ojú ogun pẹ̀lu àwọn ọmọ ogun ogún ọ̀kẹ́ (40,000) ọkùnrin alágbára, Jéróbóámù sì fa ìlà ogun sí i pẹ̀lu ogójì ọ̀kẹ́ (8,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.
4
Ábíjà dúró lórí òkè Ṣémáráímù ní òkè orílẹ̀ èdè Éfiráímù, ó sì wí pé, Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ mi!
5
Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé OLÚWA Ọlọ́run fún Dáfídì àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?
6
Síbẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, oníṣẹ́ Sólómónì ọmọ Dáfídì, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.
7
Àwọn ènìyàn lásán aláìwúlò péjọ yí i ká, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Réhóbóámù ọmọ Sólomónì ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fún ra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.
8
“Nísinsìn yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba OLÚWA, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dáfídì. Ìwọ jẹ́ ọmọ ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lu rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jéróbóámù dà láti se Ọlọ́run yín.
9
Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Ọlọ́run jáde, àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ará Léfì. Tí ó sì se àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà èyí tí kì í ṣe àwọn Ọlọ́run.
10
“Ní ti àwa, OLÚWA ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfaà tí ó ń sin OLÚWA jẹ́ àwọn ọmọ Árónì àwọn ará Léfì sì n ràn wọ́n lọ́wọ́.
11
Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọrẹ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú OLÚWA. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
12
Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò dún dídùn ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Ísírẹ́lì, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ OLÚWA Ọlọ́run baba a yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”
13
Nísinsìn yìí, Jéróbóámù ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà ní wájú Júdà, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn.
14
Nígbà tí Júdà sì bojúwo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwáju àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe OLÚWA, àwọn àlùfáà sì fun ìpè
15
Olúkúlùkù, ọkùnrin Júdà sì hó: ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Júdà sì ti hó, ni Ọlọ́run kọlu Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà àti Júdà.
16
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sálọ kúrò níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́.
17
Ábíjà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdàmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Ísírẹ́lì.
18
Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Júdà sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wọn.
19
Ábíjà sì lépa Jéróbóámù, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Bétílì pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣánà pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Éufúráímù pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀.
20
Bẹ́ẹ̀ ní Jéróbóámù kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Ábíjà. OLÚWA sì lù ú ó sì kú.
21
Ábíjà sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́talá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndinlógún.
22
Àti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti ìwà rẹ̀, àti iṣẹ́ rẹ̀, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtumọ̀ Ididì, wòlíì Ídò.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36