bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 14
2 Chronicles 14
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 15 →
1
Ábíjà sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì. Ásà ọmọ rẹ̀ rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀ èdè wà ní àlàáfíà fún ọdun mẹ́wàá.
2
Ásà ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀.
3
Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga. Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn òpó Áṣérà bolẹ̀.
4
Ó pa á láṣẹ fún Júdà láti wá OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ.
5
Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Júdà. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀.
6
Ó mọ àwọn ìlu ààbò ti Júdà, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lu rẹ̀ nígbà àwọn ọdun wọ̀n yẹn. Nítorí OLÚWA fún un ní ìsinmi.
7
“Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí” Ó wí fún Júdà, “Kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ile ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti bèrè lọ́wọ́ OLÚWA Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.
8
Ásà ní àwọn ọmọ ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin láti Júdà. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) láti Béńjamẹ́nì wọ́n dira pẹ̀lú àwọn apata kékèké àti àwọn ọrun. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin.
9
Ṣérà ará Kúṣì yàn láti dojú kọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ ogun pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Máréṣà.
10
Ásà jáde lọ lati lọ bá a. Wọ́n sì mú ibi ogun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣéfátanì lẹ́bá Máréṣà.
11
Nígbà náà, Ásà ké pe OLÚWA Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé “OLÚWA kò sí ẹnìkan bí ì rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́láti dójú kọ ẹni ńlá. Ràn wá lọ́wọ́, OLÚWA Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí. OLÚWA, ìwọ ni Ọlọ́run wa; má se jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ.”
12
OLÚWA lu àwọn ará Kúsì bolẹ̀ níwájú Ásà àti Júdà. Àwọn ará Kúsà sá lọ.
13
Ásà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gérárì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kúṣì ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́. A fún wọn pa níwájú OLÚWA àti ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọkùnrin Júdà kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógún.
14
Wọ́n pa gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní ẹ̀bá Gérárì, nítorí tí ìpayà OLÚWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí wọn. Wọ́n kó gbogbo ìkógún àwọn ìletò yìí lọ, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ìkógun ti wà níbẹ̀.
15
Wọ́n kọ lu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́-ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ. Nígbà náà wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36