bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 15
2 Chronicles 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 16 →
1
Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ásáríyà ọmọ Ódédì.
2
Ó jáde lọ bá Ásà, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Ásà, àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì. OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ silẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
3
Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Ísírẹ́lì ti wà láì sin Ọlọ́run òtitọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láì ní òfin.
4
Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si OLÚWA Ọlọ́run Isírẹ̀lì, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn.
5
Ní ọjọ́ wọ̀nnì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá
6
Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlu kan sí òmíràn nítorí OLÚWA ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú.
7
Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì se sú ọ. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ”
8
Nígbà tí Ásà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ódédì wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó gbé àwọn òrìsà ìkóríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní ori òkè Éfúráímù. Ó tún pẹpẹ OLÚWA ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé OLÚWA
9
Nígbà naà, ó pe gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ àti àwọn ènìyàn láti Éfúráímù, Mánásè àti Síméónì tí ó ti ṣe àtìpó ní àárin wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nigbà tí wọ́n rí i wí pé OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀
10
Wọ́n péjọ sí Jérúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀dógún ti ìjọba Ásà.
11
Ní àkókò yìí, wọ́n rúbọ sí OLÚWA ọgọ́rùnún méje akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún ḿéje (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkogun tí wọ́n ti kó padà.
12
Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn.
13
Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá OLÚWA Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.
14
Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún OLÚWA àti pẹ̀lú ìhó nla àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè.
15
Gbogbo Júdà yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, OLÚWA sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri
16
Ọba Ásà rọ ìyá ńlá rẹ̀ Mákà lóyè láti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá ọba nítorí tí ó ti ṣe òpó Áṣérà tí ń lé ni sá. Ásà gé òpó náà lulẹ̀, wòó, ó sì jóo ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.
17
Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Ísírẹ́lì; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Ásà wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.
18
Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.
19
Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùndínlógójì ti ìjọba Ásà.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
Recommended Reading
Commentary
2 Chronicles Commentaries
→
Devotional
2 Chronicles Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→