bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 2
2 Chronicles 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 3 →
1
Sólómónì pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀
2
Sólómónì sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.
3
Sólómónì rán iṣẹ́ yìí sí Hírámíà ọba Tírè: “Rán àwọn igi kédárì sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dáfídì. Nígbà tí ó fi igi kédárì ránsẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.
4
Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ OLÚWA Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà-ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún síse ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti òṣùpá tuntun àti ní àpèjọ OLÚWA Ọlọ́run wa. Èyí ni àsẹ fún Ísírẹ́lì láéláé.
5
“Ilé OLÚWA tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn Ọlọ́run mìíràn lọ.
6
Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún OLÚWA, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò ti le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún OLÚWA, àyàfi ibi kan fún sísun ẹbọ níwájú rẹ̀?
7
“Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní awọ̀ oju ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú isẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí Baba à mi Dáfídì pèsè.
8
“Fi igi òpépé ránṣẹ́ sí mi, pínì àti lígúmì àwọn igi láti Lébánónì, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.
9
Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nitorí ilé OLÚWA tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀.
10
Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin onígi tí ó ń gé rírẹ́ náà ni ẹgbẹ̀rún kórísì (1,000), àlìkámà ilẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) kórísì ti bálì; ẹgbẹ́rùn lọ́nà (20,000) ogún ìwẹ̀ ọtí wáìnì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìwẹ̀ òróró Ólífì.”
11
Hírámù ọba Tírè fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Sólómónì: “Nítorí tí OLÚWA fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti se ọ́ ní ọba wọn.”
12
Hírámì fi kún un pe: “Ìyìn ni fún OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dáfídì ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti àkíyèsí, tí yóò kọ́ ilé fún OLÚWA àti ààfin fún ara rẹ̀.
13
“Èmi ń rán Húrámì-Abi, sí ọ ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ ńlá,
14
Ẹni tí ìyá rẹ̀ wá láti Dánì àti tí Baba a rẹ̀ wá láti Tírè. A kọ́ ọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti igi, àti pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ ọ̀run àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára. Ó ní ìmọ̀ nínú gbogbo oríṣìí iṣẹ́ fínfín. Ó sì le ṣe àwárí irú ẹ̀yà kẹ́yà tí a bá fún un. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà pẹ̀lú àwọn ènìyàn OLÚWA mi, Dáfídì baba a rẹ.
15
“Nísinsin yìí, jẹ́ kí OLÚWA mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àlìkámọ̀ àti bálì àti òróró Ólífì náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí.
16
Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lébanónì tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Jópà. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.”
17
Sólómónì ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dáfídì ti ṣe; a sì ka iye wọn sí (153,600) ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbéjì-lélọ́gbọ̀n.
18
Ó sì yan ẹgbàá márùndínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbéjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36