bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 4
2 Chronicles 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 5 →
1
Ó se pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga.
2
Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún sì ni gíga rẹ̀.
3
Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.
4
Okùn náà dúró lóri akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárin.
5
Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dà bí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dógun ìwẹ̀ dúró.
6
Ó ṣe pọnunpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúṣù àti márùn ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ọrẹ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo òkun fún fífọ nǹkan.
7
Ó ṣe ìgbe fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé OLÚWA márùn un ní ìhà gúsù àti márùn ún ní ìhà àríwá.
8
Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé OLÚWA, márùn un ní gúṣù àti márùn ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rún ọpọ́n ìbùwọ̀n wúrà.
9
Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.
10
Ó gbé òkun náà ka orí ìhà gúsù ní ẹ̀bá Igun gúsù àríwá.
11
Ó ṣe àwọn kòkò pẹ̀lu, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni Húrámì parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Sólómónì ní ilé Ọlọ́run:
12
Àwọn òpó méje; àwọn ọpọ́n méjì rìbìtì tí ó wà lóri òpó méjèèje náà; àti ìṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì láti bo ọpọ́n rìbìtì náà tí ó wà lórí àwọn òpó naà;
13
Ọgọ́rùn ún mẹ́rin Pomígíránátì fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì naà, ẹṣẹ̀ méjì Pomigiranati ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lóri àwọn òpó náà;
14
Ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;
15
Agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀;
16
Àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fara pẹ́ẹ. Gbogbo ohun èlò ti Húrámí-bì fi idẹ dídán ṣe fún Sólómónì ọba, fún ilé OLÚWA jẹ́ idẹ dídán.
17
Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì ní àárin méjì Súkótì àti Ṣárétánì.
18
Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Sólómónì ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ̀n.
19
Sólómónì pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run: pẹpẹ wúrà tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀;
20
Àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;
21
Pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú (ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn);
22
Pẹ̀lú àlùmágàjí fìtílà, àti àwo-kòtò àti ṣíbí àti àwo-kòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹ́ḿpìlì: àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn àbáwọ inú gbọ̀ngàn ńlá.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36