bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 8
2 Chronicles 8
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 9 →
1
Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Sólómónì kọ́ ilé OLÚWA àti ilé òun fúnrarẹ̀.
2
Sólómónì tún ìlú tí Hírámù ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀.
3
Nígbà náà Sólómónì lọ sí Hámátì Sóbà ó sì borí rẹ̀.
4
Ó sì tún kọ́ Tádímórì ní ihà àti gbogbo ìlú ìsúra tí ó ti kọ́ ní Hámátì.
5
Ó sì tún kọ́ òkè Bẹti Hórónì àti ìsàlẹ̀ Bétì Hórónì gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá-ìdábùú.
6
Àti gẹ́gẹ́ bí Bálátì àti gbogbo ìlú Ìṣúra, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹsin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jérúsálẹ́mù, ní Lẹ́bánónì àti ní gbogbo àyíká agbégbé tí ó ń darí.
7
Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hítì, ará Ámórò, ará Pérísì, ará Hífì àti ará Jébúsì (Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Ísírẹ́lì),
8
Èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò parun àwọn ni Sólómónì bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.
9
Ṣùgbọ́n Solómónì kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ísírẹ́lì, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́.
10
Wọ́n sì tún jẹ́ olórí alásẹ fún ọba Sólómónì àádọ́ta ó lé nígba àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn (250).
11
Sólómónì gbé ọmọbìnrin Fáráò sókè láti ìlú Dáfídì lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí OLÚWA bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”
12
Lórí pẹpẹ OLÚWA tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Sólómónì sì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí OLÚWA,
13
Nípa ìlànà ojojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Mósè wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àkàrà àìwú, ní àjọ ọ̀ṣẹ̀ méje àti àjọ ìpàgọ́.
14
Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dáfídì, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùsọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà, nítorí èyí ni Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.
15
Wọn kò sì yà kúrò nínú àṣẹ ọba sí àwọn àlùfáà tàbí sí àwọn ọmọ Léfì, sí òràn kọ̀ọ̀kan, àti pẹ̀lú ti ìṣúra.
16
Gbogbo iṣẹ́ Sólómónì ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA lé lẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé OLÚWA sì parí.
17
Nígbà náà ni Sólómónì lọ sí Ésíónì Gébérì àti Élótì àti sí etí òkun Édómù.
18
Húrámù sì fi ọ̀kọ̀ ránsẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Sólómónì, lọ sí Ófírì wọ́n sì gbé àádọ́ta irinwó tálẹ́ntì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Sólómónì wá.
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36