bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 26
2 Chronicles 26
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 27 →
1
Nígbà náà gbogbo ènìyàn Júdà mú Ùsáyà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún (16) wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Ámásíà.
2
Òun ni ẹni náà tí ó tún Élótù kọ́, ó sì mú padà sí Júdà Lẹ́yìn ìgbà tí Ámásíà ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
3
Ùsáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláadọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekolíà; ó sì wá láti Jérúsálẹ́mù.
4
Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Ámásíà ti ṣe.
5
Ó sì wá OLÚWA ní ọjọ́ Sekaríà, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ̀n ọjọ́ tí ó wá ojú OLÚWA, Ọlọ́run fún-un ní ohun rere.
6
Ó sì lọ sí ogun lórí Fílístínì ó sì wó odi Gátì lulẹ̀, Jábìnè àti Ásídódù. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Ásídódù àti níbì kan láàrin àwọn ará Fílístínì.
7
Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lóri àwọn ará Fílístínì àti Árábù tí ń gbé ní Gúrì Bálì àti lórí àwọn ará Méhúmì.
8
Àwọn ará Ámórì gbé ẹ̀bùn wá fún Usíà, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Éjíbítì, nítorí ó ti di alágbára ńlá.
9
Ùsáyà sì kọ́ ìlú sí Jérúsálẹ́mù níbi ẹnu bodè igun, àti nibi ẹnu bodè àfonífojì àti nibi ìṣẹ́po-odi ó sì mú wọn le
10
Ó sì tún ilé ìṣọ́ ihà kọ́, ó sì gbẹ́ kàǹga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbààjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.
11
Úsíà sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jégíélì akọ̀wé àti Máséía ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hánánì, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun.
12
Àpapọ̀ iye olórí àwọn baba lórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀ta (2,600).
13
Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dogún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀.
14
Ùsáyà sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ ogun.
15
Ní Jérúsálẹ́mù ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun tí ó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ihumọ̀ ọlọgbọ́n ọkùnrin fún lílò lórí ilé-ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.
16
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ùsáyà jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìsòótọ́ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wo ilé OLÚWA láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.
17
Ásáríyà àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà OLÚWA mìíràn sì tẹ̀lée.
18
Wọ́n sì takòó, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ùsáyà, láti sun tùràrí sí OLÚWA. Èyi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìsòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run.”
19
Ùsía, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣe tán láti sun tùràrí, ó sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé OLÚWA, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀.
20
Nígbà tí Ásáríyà olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì ríi wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lú pẹ̀lú, òun tìkálárarẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí OLÚWA ti lùú.
21
Ọba Ùsíá sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé ọ̀tọ̀ adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ile OLÚWA. Jótamù ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
22
Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Ùsía láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Ìsàíà ọmọ Ámósì.
23
Ùsáyà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀,” Jótamù ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 27 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
Recommended Reading
Commentary
2 Chronicles Commentaries
→
Devotional
2 Chronicles Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→