bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Chronicles 16
2 Chronicles 16
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 17 →
1
Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Básà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá sí Júdà ó sì kọlu Rámà, láti ma bàá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Ásà ọba Júdà lọ.
2
Nígbà náà ni Ásà mú wúrà àti fàdákà jáde ninú ilé ìsúra ilé OLÚWA àti ààfin ọba ó sì ránsẹ́ sí Bẹni-Hádádì ọba Árámù, ẹni tí ń gbé ní Dámásíkù, ó wí pé,
3
“Májẹ̀mu kan wà láàrin èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrin baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránsẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mu tí o bá Básà ọba Ísirẹ́lì dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi”
4
Bẹni-hádádì sì gbọ́ ti Ásà ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì kọlu Íjónì, Dánì, Abeli-Máímù, àti gbogbo ilú ìsúra Náfítalì.
5
Nígbà tí Básà gbọ́ èyi, ó sì dá kíkọ́ Rámà dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró.
6
Nígbà náà ní ọba Ásà kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rámà lọ èyí ti Básà ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Gébà àti Mísípà.
7
Ní àkókò náà wòlíì Hánánì wá sí ọ̀dọ̀ Ásà ọba Júdà, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ọba Árámù, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀ lé OLÚWA Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Árámù ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
8
Àwa kì í ṣe ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà àwọn alágbára ogun pẹ̀lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ.
9
Nítorí ojú OLÚWA yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”
10
Ásà sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Ásà sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
11
Àwọn iṣẹ́ ìjọba Ásà, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Júdà àti Ísírẹ́lì.
12
Ní ọdún kọkàndínlógójì (39) ìjọba rẹ̀, Ásà sì ṣe àìsàn pẹ̀lú àrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Lákókò àrùn rẹ̀ ó múná, kó dà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ OLÚWA, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.
13
Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Ásà kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀,
14
Wọ́n sì sin ín sínú ìsà òkú tí ó ti gbé jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dáfídì. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dìdùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n àwọn alápòlù pèsè, wọ́n sì ṣe ìjóná ńlá nínú ọlá ńlá rẹ̀.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36