bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 1
Isaiah 1
Yoruba 2010
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 2 →
1
Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda.
2
Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀ Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ, tí mo tọ́ wọn dàgbà tán, ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi.
3
Mààlúù mọ olówó rẹ̀; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un; ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan, òye kò yé àwọn eniyan mi.”
4
Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ, ìran oníṣẹ́ ibi; àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́! Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹli wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i.
5
Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni, àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò, gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì.
6
Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín, kò síbìkan tí ó gbádùn. Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.
7
Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro, wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín. Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín. Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀.
8
Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà, ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí; ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì.
9
Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni, à bá rí bí i Sodomu, à bá sì dàbí Gomora.
10
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ìjòyè Sodomu: Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa, ẹ̀yin ará Gomora
11
OLUWA ní, “Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi? Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́; bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa. N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.
12
Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi, ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.
13
Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́; ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi. Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ. Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.
14
Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín. Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi, n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.
15
“Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura, n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbadura n kò ní gbọ́; nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,
16
Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká. Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.
17
Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere. Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́. Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́. Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”
18
OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀. Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná, yóo di funfun bí ẹfun. Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì, yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.
19
Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn, ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà.
20
Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun; idà ni yóo run yín.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.
21
Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó, ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn.
22
Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́. Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.
23
Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè; gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri. Wọn kì í gbèjà aláìníbaba, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.
24
Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní: “N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi, n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.
25
Nígbà tí mo bá gbá ọ mú, n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù. N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.
26
N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀. Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ, lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”
27
A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada; a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.
28
Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run, àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.
29
Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ. Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn.
30
Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé, ati bí ọgbà tí kò lómi.
31
Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná. Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66