bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 43
Isaiah 43
Yoruba 2010
← Chapter 42
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 44 →
1
Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu, gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí, Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ. Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada; mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.
2
Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.
3
Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ. Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada, mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ.
4
Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ, mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ; mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.
5
Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn, n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
6
N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀.’ N óo sọ fún ìhà gúsù pé, ‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’ Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè, sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé,
7
gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, àwọn tí mo dá fún ògo mi, àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”
8
Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde, àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́, wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.
9
Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ, kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀. Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá; kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́, kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”
10
OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn; kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́, kí ó sì ye yín pé, Èmi ni. A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi, òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.
11
“Èmi ni OLUWA, kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi.
12
Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là, mo sì ti kéde, nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín; ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
13
Èmi ni Ọlọrun, láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni. Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi: Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”
14
OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní, “N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín, n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè, ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.
15
Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín, Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”
16
OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun, tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;
17
ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun; wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́, wọ́n kú bí iná fìtílà.
18
ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́, kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.
19
Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun ó ti yọ jáde nisinsinyii, àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀? N óo la ọ̀nà ninu aginjù, n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.
20
Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:
21
Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi, kí wọ́n lè kéde ògo mi.
22
“Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
23
Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi, tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi. N kò fi tipátipá mu yín rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá.
24
Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi, tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu, ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín.
25
Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, nítorí ti ara mi; n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.
26
“Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn; ẹ ro ẹjọ́ tiyín, kí á lè da yín láre.
27
Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀, àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí.
28
Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun; mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”
← Chapter 42
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 44 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66