bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 9
Isaiah 9
Yoruba 2010
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 10 →
1
Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.
2
Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.
3
Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà. Ó ti fi kún ayọ̀ wọn; wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè. Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.
4
Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn, ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká, ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n. Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.
5
Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun, ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun, iná yóo sì jó wọn run.
6
Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.
7
Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí
8
OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu, àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli.
9
Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀, àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria, àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé:
10
Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀? Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́. Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó, ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn.
11
Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn: Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn:
12
Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn, ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn; wọn óo gbé Israẹli mì. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
13
Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun.
14
Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù.
15
Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí, àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù
16
Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.
17
Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn, àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun, ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
18
Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná, tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.
19
Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná, àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.
20
Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́, sibẹ ebi ń pa wọ́n. Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì, sibẹ wọn kò yó, àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ.
21
Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà. Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66