bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 8
Isaiah 8
Yoruba 2010
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 9 →
1
Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún mi pé, “Mú ìwé kan tí ó fẹ̀, kí o kọ Maheriṣalali-haṣi-basi sí i lórí gàdàgbà gàdàgbà.”
2
Mo bá pe Alufaa Uraya ati Sakaraya, ọmọ Jebẹrẹkaya, kí wọn wá ṣe ẹlẹ́rìí mi nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.
3
Nígbà tí mo bá iyawo mi, tí òun náà jẹ́ wolii lò pọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin. OLUWA bá sọ fún mi pé kí n sọ ọmọ náà ní Maheriṣalali-haṣi-basi.
4
Nítorí kí ọmọ náà tó mọ bí a tí ń pe ‘Baba mi’ tabi ‘Mama mi’, wọn óo ti kó àwọn nǹkan alumọni Damasku ati ìkógun Samaria lọ sí Asiria.
5
OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀ ó ní,
6
“Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya,
7
nítorí náà, ẹ wò ó, OLUWA yóo gbé ọba Asiria ati gbogbo ògo rẹ̀ dìde wá bá wọn, yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí omi odò Yufurate, tí ó kún àkúnya, tí ó sì kọjá bèbè rẹ̀.
8
Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.”
9
Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ! A óo fọ yín túútúú. Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè. Ẹ di ara yín ní àmùrè; a óo fọ yín túútúú. Ẹ di ara yín ní àmùrè, a óo fọ yín túútúú.
10
Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo. Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán. Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa.
11
Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní,
12
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù.
13
OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà.
14
Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu.
15
Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.”
16
Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi.
17
N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀.
18
Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni.
19
Nígbà tí wọ́n bá wí fun yín pé kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àjẹ́ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tí wọn ń jẹ ẹnu wúyẹ́-wúyẹ́. Ṣé kò yẹ kí orílẹ̀-èdè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun wọn? Ṣé lọ́dọ̀ òkú ni ó ti yẹ kí alààyè ti máa wádìí ọ̀rọ̀?
20
Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.
21
Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè.
22
Wọn óo bojú wo ilẹ̀, kìkì ìdààmú ati òkùnkùn ati ìṣúdudu ati ìnira ni wọn óo rí. A óo sì sọ wọ́n sinu òkùnkùn biribiri.
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66