bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 29
Isaiah 29
Yoruba 2010
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 30 →
1
Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun! Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí. Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i, ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn.
2
Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun. Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀, bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi.
3
N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíká n óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́; n óo sì mọ òkítì sára odi yín.
4
Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀, láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀. A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú, a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀.
5
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn, ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.
6
Lójijì, kíá, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín, pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá; ati ààjà, ati ìjì líle, ati ahọ́n iná ajónirun.
7
Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà, yóo parẹ́ bí àlá, gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà, tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru.
8
Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun, tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun, tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlá pé òun ń mu omi ṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.
9
Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀, kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀. Ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ sì di afọ́jú. Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí. Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle.
10
Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú; ó ti bo orí ẹ̀yin aríran.
11
Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú, bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò lè kà á nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í.
12
Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò mọ̀wé kà.
13
OLUWA ní, “Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi, ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí; ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi. Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.
14
Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi, ohun ìyanu tí ó jọni lójú. Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.”
15
Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé; àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn, tí ń wí pé, “Ta ló rí wa? Ta ló mọ̀ wá?”
16
Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò. Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀? Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé: “Kìí ṣe òun ló ṣe mí.” Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé: “Kò ní ìmọ̀.”
17
Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kù tí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi eléso a óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó.
18
Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé, ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀.
19
Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA. Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli
20
nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán, àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo; àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun;
21
àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀, tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà, tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan.
22
Nítorí náà, OLUWA tí ó ra Abrahamu pada sọ nípa ilé Jakọbu pé, “Ojú kò ní ti Jakọbu mọ́ bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23
Nítorí nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi láàrin wọn, wọn óo fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi. Wọn óo bọ̀wọ̀ fún Ẹni Mímọ́ Jakọbu; wọn óo sì bẹ̀rù Ọlọrun Israẹli.
24
Àwọn tí ó ti ṣìnà ninu ẹ̀mí yóo ní òye; àwọn tí ń kùn yóo sì gba ẹ̀kọ́.”
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66