bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 32
Isaiah 32
Yoruba 2010
← Chapter 31
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 33 →
1
Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo, àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́.
2
Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jà Wọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀, ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru.
3
Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i, etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di.
4
Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye, àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete.
5
A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki.
6
Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi. Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun, tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA; tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ, tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ.
7
Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan. Wọn a máa pète ìkà, láti fi irọ́ pa àwọn talaka run, kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre.
8
Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere, ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn.
9
Ẹ dìde, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀, ẹ gbóhùn mi; ẹ̀yin ọmọbinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra, ẹ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.
10
Ní nǹkan bíi ọdún kan ó lé díẹ̀ sí i ẹ̀yin obinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra; ẹ ó rí ìdààmú nítorí pé àkókò ìkórè yóo kọjá, èso àjàrà kò sì ní sí lórí igi mọ́.
11
Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀, kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra, ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò; kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀.
12
Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára, ati nítorí àwọn àjàrà eléso;
13
nítorí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n ati ẹ̀gún ọ̀gàn ni ó ń hù lórí ilẹ̀ àwọn eniyan mi. Bákan náà, ẹ káàánú fún àwọn ilé aláyọ̀ ninu ìlú tí ó kún fún ayọ̀,
14
nítorí pé àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ààfin, ìlú yóo tú, yóo di ahoro. Òkè ati ilé ìṣọ́ yóo di ibùgbé àwọn ẹranko títí lae, yóo di ibi ìgbádùn fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, ati pápá ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.
15
Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí, títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wá títí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso, tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó.
16
A óo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ní gbogbo ilẹ̀ náà, ìwà òdodo yóo sì wà níbi gbogbo.
17
Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa, ati igbẹkẹle OLUWA títí lae.
18
Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia, ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà.
19
Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀, a óo sì pa ìlú náà run patapata.
20
Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀, ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri.
← Chapter 31
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 33 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66