bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 16
Isaiah 16
Yoruba 2010
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 17 →
1
Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀, wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni.
2
Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni, wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn, wọ́n ń lọ sókè, sódò, bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́.
3
“Gbà wá ní ìmọ̀ràn, máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa. Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá, kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan, bí ẹni pé alẹ́ ni. Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde; má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ.
4
Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín. Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.” Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin, tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà.
5
Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà, Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi.
6
A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu, bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ: ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.
7
Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún, kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu. Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi, tí ó ní èso àjàrà ninu.
8
Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni; bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma: àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀, èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀. Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀, wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.
9
Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibuma bí mo ṣe sọkún fún Jaseri; mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale, mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrò nítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.
10
Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso; ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn. Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́.
11
Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu, ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi.
12
Nígbà tí Moabu bá wá siwaju, tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀, títí ó fi rẹ̀ ẹ́, adura rẹ̀ kò ní gbà.
13
Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí.
14
Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66