bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 48
Isaiah 48
Yoruba 2010
← Chapter 47
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 49 →
1
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè, ọmọ bíbí inú Juda, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra, tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.
2
Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́, ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
3
OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde, àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, èmi ni mo sọ wọ́n jáde, tí mo sì fi wọ́n hàn. Lójijì mo ṣe wọ́n, nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ.
4
Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín, olóríkunkun sì ni yín pẹlu.
5
Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́: kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín, kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n, àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’
6
“Ẹ ti fetí ara yín gbọ́, nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀? Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.
7
Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn, ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní. Kí ẹ má baà wí pé: Wò ó, a mọ̀ wọ́n.
8
Ẹ kò gbọ́ ọ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí, nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè, ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀, láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.
9
“Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi, nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín, kí n má baà pa yín run.
10
Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́, ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka, mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú.
11
Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́, n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn.
12
“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu, ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè, Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀, èmi sì ni ẹni òpin.
13
Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run. Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta.
14
“Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́, èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi? OLUWA fẹ́ràn rẹ̀, yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni, yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea.
15
Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é, èmi ni mo mú un wá, yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀.
16
Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí, láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.” Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi.
17
OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani, tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà.
18
“Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi, alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò, òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun.
19
Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn, arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà. Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé, bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.”
20
Ẹ jáde kúrò ní Babiloni, ẹ sá kúrò ní Kalidea, ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀, ẹ kéde rẹ̀, ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé “OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.”
21
Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde.
22
OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”
← Chapter 47
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 49 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66