bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 14
Isaiah 14
Yoruba 2010
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 15 →
1
OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu.
2
Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára.
3
Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe,
4
ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé: “Agbára aninilára ti pin ìpayà ojoojumọ ti dópin.
5
OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi, ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí
6
tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró, tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́.
7
Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafia wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀.
8
Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín; àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé, ‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀, kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’
9
“Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé. Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ, àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn, Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.
10
Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé, ‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà. Ẹ ti dàbí i wa.
11
A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú. Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lórí àwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’
12
“Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run, ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀! Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀, ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí.
13
Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.
14
N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run, n óo wá dàbí Olodumare.’
15
Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú, sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
16
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ, wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé, ‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí, tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;
17
ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀, tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run, ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’
18
Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọn olukuluku ninu ibojì tirẹ̀.
19
Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ, bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé, tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù; tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun; àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta, bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.
20
A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù, nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run, o sì ti pa àwọn eniyan rẹ. Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae!
21
Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, kí wọn má baà tún gbógun dìde, kí wọn gba gbogbo ayé kan, kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.”
22
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn.
23
N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
24
OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní, “Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí; ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ.
25
Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi; n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi. Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi, ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí.
26
Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí, mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.”
27
OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu; ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada? Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣe ta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?
28
Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:
29
Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini, ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín; nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò, ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.
30
Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ, aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu. Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ, a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.
31
Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè, kí ìwọ ìlú sì figbe ta. Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá, kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn.
32
Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini? A óo sọ fún wọn pé, “OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀ àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66