bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 45
Isaiah 45
Yoruba 2010
← Chapter 44
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 46 →
1
Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí: Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò, láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀, láti tú àmùrè àwọn ọba, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀, kí ẹnubodè má lè tì.
2
OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ, n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀; n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin.
3
N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn, ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀; kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.
4
Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi, ati Israẹli, àyànfẹ́ mi, mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí.
5
“Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn, kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí.
6
Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.
7
Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn, èmi ni mo dá alaafia ati àjálù: Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
8
Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run, kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde. Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu, èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀.
9
“Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé! Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà. Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé: ‘Kí ni ò ń mọ?’ Tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’
10
Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé: ‘Irú kí ni o bí?’ Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé: ‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’ Olúwarẹ̀ gbé!”
11
OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni, “Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni, tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi?
12
Èmi ni mo dá ayé, tí mo dá eniyan sórí rẹ̀. Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.
13
Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi, n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́; òun ni yóo tún ìlú mi kọ́, yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀, láìgba owó ati láìwá èrè kan.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.
14
Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia, ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀, wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ, wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ. Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn, wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ. Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé, ‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà, kò tún sí Ọlọrun mìíràn. Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”
15
Nítòótọ́, ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́, Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà.
16
Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì, ìdààmú yóo sì bá wọn. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère yóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.
17
Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là, títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀. Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae.
18
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.) Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò dá a ninu rúdurùdu, ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀ Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.
19
N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn. N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé: ‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’ Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ. Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”
20
OLUWA ní: “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá, ẹ jọ súnmọ́ bí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè. Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri, tí wọ́n sì ń gbadura sí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.
21
Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín, jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀. Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae? Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́? Ṣebí èmi OLUWA ni? Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlà kò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi.
22
“Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là, gbogbo ẹ̀yin òpin ayé. Nítorí èmi ni Ọlọrun, kò tún sí ẹlòmíràn mọ́.
23
Mo ti fi ara mi búra, mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú, ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada: ‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi, èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’
24
“Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé, ‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’ Gbogbo àwọn tí ń bá a bínú yóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú.
25
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun, wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA.
← Chapter 44
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 46 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66