bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Isaiah 57
Isaiah 57
Yoruba 2010
← Chapter 56
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 58 →
1
Olódodo ń ṣègbé, kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i. A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé, pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.
2
Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia, wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.
3
Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi, ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́, ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.
4
Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sí tí ẹ yọ ṣùtì sí? Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín irú ọmọ ẹ̀tàn;
5
ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku, ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì, ati ní abẹ́ àpáta?
6
Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì, àwọn ni ẹ̀ ń sìn, àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí, àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí. Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?
7
Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ sí níbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.
8
O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn. O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀. O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀, ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.
9
O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki, o kó ọpọlọpọ turari lọ, o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.
10
Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà, sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.” Ò ń wá agbára kún agbára, nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.
11
Ta ni ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́; tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi? Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́, ni o kò fi bẹ̀rù mi?
12
N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
13
Nígbà tí o bá kígbe, kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́. Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí, ni yóo ni ilẹ̀ náà, òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.
14
OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe, ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”
15
Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí.
16
Nítorí n kò ní máa jà títí ayé, tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo: nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde, Èmi ni mo dá èémí ìyè.
17
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi, mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi; sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.
18
Mo ti rí bí ó ti ń ṣe, ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn; n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu, n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.
19
Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè, ati àwọn tí ó wà nítòsí; n óo sì wò wọ́n sàn.
20
Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun, nítorí òkun kò lè sinmi, omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.
21
Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.
← Chapter 56
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 58 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66