bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 1
Proverbs 1
Yoruba 2010
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 2 →
1
Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa,
2
kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́, kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn,
3
láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n, òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú,
4
láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n, kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́,
5
kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu.
6
Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀.
7
Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́.
8
Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ, má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ,
9
nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ, ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
10
Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà.
11
Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa ká lọ, kí á lọ sápamọ́ láti paniyan, kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,
12
jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,
13
a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó, ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.
14
Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa, kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”
15
Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́, má sì bá wọn rìn,
16
nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí, wọ́n a sì máa yára láti paniyan.
17
Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀, nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,
18
ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè, ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.
19
Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí, ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.
20
Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà, ó ń pariwo láàrin ọjà,
21
ó ń kígbe lórí odi ìlú, ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní,
22
“Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín? Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn, tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?
23
Ẹ fetí sí ìbáwí mi, n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín, n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.
24
Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́, mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn,
25
ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì, ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi.
26
Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ín nígbà tí ìdààmú bá dé ba yín, n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà nígbà tí ìpayà bá dé ba yín.
27
Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì, tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle, tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀.
28
Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, ṣugbọn n kò ní dáhùn. Ẹ óo wá mi láìsinmi, ṣugbọn ẹ kò ní rí mi.
29
Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀, ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.
30
Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi, ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi.
31
Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín, ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára.
32
Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́ aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run.
33
Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ tèmi, yóo máa wà láìléwu, yóo máa gbé pẹlu ìrọ̀rùn, láìsí ìpayà ibi.”
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31