bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 16
Proverbs 16
Yoruba 2010
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
1
Èrò ọkàn ni ti eniyan ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn.
2
Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀, ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn.
3
Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.
4
OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́, ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu.
5
OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga, dájúdájú kò ní lọ láìjìyà.
6
Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.
7
Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn, a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.
8
Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.
9
Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
10
Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀, ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde.
11
Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.
12
Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe, nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀.
13
Inú ọba a máa dùn sí olódodo, ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́.
14
Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba, ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.
15
Ìyè wà ninu ojurere ọba, ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀.
16
Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ, ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ.
17
Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi, ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.
18
Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun, agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.
19
Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talaka ju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ.
20
Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn, ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.
21
Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye, ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada.
22
Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i, agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀.
23
Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada.
24
Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin, a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá.
25
Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan, ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
26
Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́, ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri.
27
Eniyan lásán a máa pète ibi, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni.
28
Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀, ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.
29
Ìkà eniyan tan aládùúgbò rẹ̀, ó darí rẹ̀ lọ sọ́nà tí kò tọ́.
30
Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa, ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde.
31
Adé ògo ni ewú orí, nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i.
32
Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.
33
À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn, ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31