bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 10
Proverbs 10
Yoruba 2010
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 11 →
1
Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí: Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀.
2
Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè, ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú.
3
OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo, ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú.
4
Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì, ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀.
5
Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè, ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè a máa kó ìtìjú báni.
6
Ibukun wà lórí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.
7
Ayọ̀ ni ìrántí olódodo, ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé.
8
Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́, ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.
9
Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.
10
Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia.
11
Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.
12
Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.
13
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye, ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.
14
Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra.
15
Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀, ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run.
16
Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè, ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀.
17
Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà.
18
Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan, ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni.
19
Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́, ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.
20
Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka, ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan.
21
Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n.
22
Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un.
23
Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀, ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye.
24
Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a, ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà.
25
Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ, ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
26
Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín, ati bí èéfín ti rí sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.
27
Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn, ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.
28
Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀, ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo.
29
OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́, ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi.
30
Gbọningbọnin ni olódodo yóo dúró, ṣugbọn ẹni ibi kò ní lè gbé ilẹ̀ náà.
31
Ẹnu olódodo kún fún ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ṣugbọn ẹnu alaiṣootọ ni a pamọ́.
32
Olódodo mọ ohun tí ó dára láti sọ, ṣugbọn ti eniyan burúkú kò ju ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31