bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 15
Proverbs 15
Yoruba 2010
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 16 →
1
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.
2
Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.
3
Ojú OLUWA wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.
4
Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.
5
Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀, ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni.
6
Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra, ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.
7
Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀, ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
8
Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA, ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.
9
OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.
10
Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere, ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.
11
Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA, mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.
12
Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí, kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.
13
Inú dídùn a máa múni dárayá, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
14
Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀, ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.
15
Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú, ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.
16
Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA, ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.
17
Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́, sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.
18
Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.
19
Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ, ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.
20
Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
21
Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.
22
Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú, ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.
23
Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀, kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!
24
Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè, kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.
25
OLUWA a máa wó ilé agbéraga, ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.
26
Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA, ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.
27
Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn, ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.
28
Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.
29
OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú, ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.
30
Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn, ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.
31
Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rere yóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.
32
Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.
33
Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31