bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 22
Proverbs 22
Yoruba 2010
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 23 →
1
Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ, kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ.
2
Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
3
Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́, ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà, ó sì kó sinu ìyọnu.
4
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.
5
Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn, ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn.
6
Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn, bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.
7
Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí, ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.
8
Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú, pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.
9
Olójú àánú yóo rí ibukun gbà, nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.
10
Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀, asọ̀ ati èébú yóo sì dópin.
11
Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́, tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́.
12
Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́, ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po.
13
Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta! Yóo pa mí jẹ lójú pópó!”
14
Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá, ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀.
15
Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde, ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde.
16
Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ, tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.
17
Tẹ́tí rẹ sílẹ̀ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ mi,
18
nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ, tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.
19
Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ, kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé.
20
Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n,
21
láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́, kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ.
22
Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka, má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.
23
Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn, yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.
24
Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́, má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.
25
Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀, kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ.
26
Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó, má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè.
27
Tí o kò bá rí owó san fún olówó, olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ.
28
Má hú ohun tí àwọn baba ńlá rẹ rì mọ́lẹ̀, tí wọ́n fi pa ààlà kúrò.
29
Ṣe akiyesi ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọba ni yóo máa bá ṣiṣẹ́, kì í ṣe àwọn eniyan lásán.
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 23 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31