bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 23
Proverbs 23
Yoruba 2010
← Chapter 22
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 24 →
1
Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára.
2
Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra, kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun.
3
Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú, nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn.
4
Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ, fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.
5
Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ, ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò, bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.
6
Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun, má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀;
7
nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni. Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!” ṣugbọn kò dé inú rẹ̀.
8
O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ, gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù.
9
Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀, nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.
10
Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́, má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;
11
nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára, yóo gba ìjà wọn jà.
12
Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
13
Bá ọmọde wí; bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú.
14
Bí o bá fi pàṣán nà án, o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú.
15
Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n, inú mi yóo dùn.
16
N óo láyọ̀ ninu ọkàn mi nígbà tí o bá ń sọ òtítọ́.
17
Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo.
18
Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára, ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.
19
Fetí sí mi, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n, darí ọkàn rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20
Má bá àwọn ọ̀mùtí kẹ́gbẹ́; tabi àwọn wọ̀bìà, tí wọn ń jẹ ẹran ní àjẹkì;
21
nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka, oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà.
22
Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ, má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i.
23
Ra òtítọ́, má sì tà á, ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu.
24
Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ, inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn.
25
Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn, jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ.
26
Ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì máa kíyèsí ọ̀nà mi.
27
Nítorí aṣẹ́wó dàbí ọ̀fìn jíjìn, obinrin onírìnkurìn sì dàbí kànga tí ó jìn.
28
A máa ba níbùba bí olè, a sì máa sọ ọpọlọpọ ọkunrin di alágbèrè.
29
Ta ló ni òṣì? Ta ló ni ìbànújẹ́? Ta ló ni ìjà? Ta ló ni asọ̀? Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú pípọ́n koko?
30
Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni, àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.
31
Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra, nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife, tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.
32
Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò, oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.
33
Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì, ọkàn rẹ á máa ro èròkerò.
34
O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun, bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀.
35
O óo wí pé, “Wọ́n lù mi, ṣugbọn kò dùn mí; wọ́n nà mí, ṣugbọn ń kò mọ̀. Nígbà wo ni n óo tó jí? N óo tún wá ọtí mìíràn mu.”
← Chapter 22
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 24 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31