bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 6
Proverbs 6
Yoruba 2010
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 7 →
1
Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì,
2
tí o bá bọ́ sinu tàkúté tí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ,
3
o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ. Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ là: lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.
4
Má sùn, má sì tòògbé,
5
gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ, àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.
6
Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ, ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n.
7
Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ
8
sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn; a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè.
9
O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ? Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun?
10
Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,
11
yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni.
12
Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri, a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè,
13
bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe.
14
Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀,
15
nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì, yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.
16
Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́: wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:
17
Ìgbéraga, irọ́ pípa, ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,
18
ọkàn tí ń pète ìkà, ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi,
19
ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́, ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.
20
Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́, má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21
Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo, kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
22
Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ, bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ, bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀.
23
Nítorí fìtílà ni òfin, ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,
24
láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú, ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀.
25
Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ.
26
Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ, ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.
27
Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà, kí aṣọ rẹ̀ má jó?
28
Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná, kí iná má jó o lẹ́sẹ̀?
29
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí, kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà.
30
Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi.
31
Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje, ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án.
32
Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí, ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun.
33
Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà, ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae.
34
Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru, kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san.
35
Kò ní gba owó ìtanràn, ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31