bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 17
Proverbs 17
Yoruba 2010
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 18 →
1
Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀, ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ.
2
Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́, yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni.
3
Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò, ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò.
4
Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi, òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà.
5
Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà.
6
Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó, òbí sì ni ògo àwọn ọmọ.
7
Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀, bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.
8
Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni, ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege.
9
Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́, ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.
10
Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́n ju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ.
11
Ọ̀tẹ̀ ṣá ni ti eniyan burúkú ní gbogbo ìgbà, ìkà òjíṣẹ́ ni a óo sì rán sí i.
12
Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ, ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ.
13
Ẹni tí ó fibi san oore, ibi kò ní kúrò ninu ilé rẹ̀ lae.
14
Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí kí eniyan ya odò tí wọn sé, dá a dúró kí ó tó di ńlá.
15
Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́bi ati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre, OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn.
16
Owó kò wúlò lọ́wọ́ òmùgọ̀ pé kí ó fi ra ọgbọ́n, nígbà tí kò ní òye?
17
Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.
18
Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́, láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19
Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀, ẹni tí ó bá fẹ́ràn kí á máa fi owó ṣe àṣehàn ń wá ìparun.
20
Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege, ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu.
21
Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n, kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀.
22
Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.
23
Eniyan burúkú a máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ níkọ̀kọ̀, láti yí ìdájọ́ po.
24
Ẹni tí ó ní òye a máa tẹjúmọ́ ọgbọ́n, ṣugbọn ojú òmùgọ̀ kò gbé ibìkan, ó ń wo òpin ilẹ̀ ayé.
25
Òmùgọ̀ ọmọ jẹ́ ìbànújẹ́ baba rẹ̀, ati ọgbẹ́ ọkàn fún ìyá tí ó bí i.
26
Kò tọ̀nà láti fi ipá mú aláìṣẹ̀ san owó ìtanràn, nǹkan burúkú ni kí á na gbajúmọ̀ tí kò rú òfin.
27
Ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ a máa kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ẹni tí ó bá jẹ́ olóye eniyan a máa ṣe jẹ́ẹ́.
28
A máa ka òmùgọ̀ pàápàá kún ọlọ́gbọ́n, bí ó bá pa ẹnu rẹ̀ mọ́, olóye ni àwọn eniyan yóo pè é, bí ó bá panu mọ́ tí kò sọ̀rọ̀.
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31