bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 20
Proverbs 20
Yoruba 2010
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 21 →
1
Ẹlẹ́yà ni ọtí waini, aláriwo ní ọtí líle, ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2
Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.
3
Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà.
4
Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò, nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.
5
Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn, ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.
6
Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́, ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?
7
Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́, ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.
8
Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù.
9
Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́, ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀?
10
Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA.
11
Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀, bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà.
12
Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
13
Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka, lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù.
14
“Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí, bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà.
15
Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.
16
Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò, gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.
17
Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan, ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.
18
Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀, gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.
19
Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí, nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́.
20
Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú, àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri.
21
Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀, kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn.
22
Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú, gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.
23
Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA, ìwọ̀n èké kò dára.
24
OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni, eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.
25
Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA, kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀.
26
Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù, a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
27
Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA, tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.
28
Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́, òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró.
29
Agbára ni ògo ọ̀dọ́, ewú sì ni ẹwà àgbà.
30
Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò, pàṣán a máa mú kí inú mọ́.
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31