bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 13
Proverbs 13
Yoruba 2010
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 14 →
1
Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.
2
Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.
3
Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.
4
Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.
5
Olóòótọ́ a máa kórìíra èké, ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.
6
Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.
7
Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan, níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka, ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
8
Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada, ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.
9
Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn, ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.
10
Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.
11
Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.
12
Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn, ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.
13
Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun, ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.
14
Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè a máa yọni ninu tàkúté ikú.
15
Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere, ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.
16
Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.
17
Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala, ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.
18
Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.
19
Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀.
20
Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.
21
Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.
22
Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.
23
Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde, ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.
24
Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.
25
Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn, ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31