bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 7
Proverbs 7
Yoruba 2010
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 8 →
1
Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ.
2
Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè, pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ,
3
wé wọn mọ́ ìka rẹ, kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.
4
Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,” kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ,
5
kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́, kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin, ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀.
6
Mo yọjú wo ìta, láti ojú fèrèsé ilé mi.
7
Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí, mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn, ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n.
8
Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà,
9
ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí, tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn.
10
Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀, ó wọ aṣọ aṣẹ́wó, ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn.
11
Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin, kì í gbélé rẹ̀.
12
Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà, yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀.
13
Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu, yóo wí pẹlu ainitiju pé,
14
“Mo ti rú ẹbọ alaafia, mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí.
15
Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ, mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ.
16
Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi.
17
Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi.
18
Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́ títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa.
19
Ọkọ mi kò sí nílé, ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn.
20
Ó mú owó pupọ lọ́wọ́, kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”
21
Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un.
22
Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e, bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa, tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,
23
títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninu bí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn, láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.
24
Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.
25
Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
26
Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀, ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa.
27
Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀, ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31