bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 9
Proverbs 9
Yoruba 2010
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 10 →
1
Ọgbọ́n ti kọ́lé, ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró.
2
Ó ti pa ẹran rẹ̀, ó ti pọn ọtí waini rẹ̀, ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀.
3
Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé:
4
“Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!” Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé,
5
“Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi, kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò.
6
Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè, kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.”
7
Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù, ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀.
8
Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí, kí ó má baà kórìíra rẹ, bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ.
9
Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i, kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀.
10
Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè.
11
Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn. Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè.
12
Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ, Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀.
13
Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n, oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú.
14
Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀, á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú.
15
A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ, àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé,
16
“Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!” Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé,
17
“Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn, oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.”
18
Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀, ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31