bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 28
Proverbs 28
Yoruba 2010
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 29 →
1
Àwọn eniyan burúkú a máa sá, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn, ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun.
2
Bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀, léraléra ni wọ́n ó máa jọba, ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ní àwọn eniyan tí wọn ní òye ati ìmọ̀, yóo wà fún ìgbà pípẹ́.
3
Talaka tí ń ni aláìní lára dàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́.
4
Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀ ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n.
5
Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké.
6
Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú sàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ.
7
Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ọmọ tí ó pa òfin mọ́, ṣugbọn ẹni tí ń bá àwọn wọ̀bìà rìn, ń dójúti baba rẹ̀.
8
Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èlé ati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú, ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka.
9
Ẹni tí ó kọ etí dídi sí òfin Ọlọrun, adura rẹ̀ pàápàá yóo di ìríra sí Ọlọ́run.
10
Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi, yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.
11
Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀, ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀.
12
Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.
13
Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.
14
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo, ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu.
15
Ọba burúkú tí ó jọba lórí àwọn talaka, dàbí kinniun tí ń bú ramúramù, tabi ẹranko beari tí inú ń bí.
16
Ìkà, aninilára ni olórí tí kò ní òye, ṣugbọn ẹ̀mí ẹni tí ó bá kórìíra à ń jèrè lọ́nà èrú yóo gùn.
17
Bí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan bá ń da eniyan láàmú, yóo di ìsáǹsá ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ràn án lọ́wọ́.
18
Ẹni tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú yóo rí ìgbàlà, ṣugbọn ẹni tí ń rìn ségesège yóo ṣubú sinu kòtò.
19
Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ, ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka.
20
Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ, ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.
21
Ojuṣaaju kò dára, sibẹ oúnjẹ lè mú kí eniyan ṣe ohun tí kò tọ́.
22
Ahun a máa sáré ati ní ọrọ̀, láìmọ̀ pé òṣì ń bọ̀ wá ta òun.
23
Ẹni tí ó bá eniyan wí, yóo rí ojurere níkẹyìn, ju ẹni tí ń pọ́n eniyan lọ.
24
Ẹni tí ó ja ìyá tabi baba rẹ̀ lólè, tí ó ní, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”, ẹlẹgbẹ́ apanirun ni.
25
Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere.
26
Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀, ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là.
27
Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní, ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún.
28
Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i.
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31